Hymn 580 – OKAN mi yo ninu Oluwa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OKAN mi yo ninu Oluwa" (C&S Hymn #580, Yoruba). ỌKAN mi yọ ninu Oluwa, 'Tori o jẹ Iye fun mi, Ohun Rẹ dun pupọ lati…
ỌKAN mi yọ ninu Oluwa, 'Tori o jẹ Iye fun mi, Ohun Rẹ dun pupọ lati gbọ, Adun ni lati r'oju Rẹ, Emi yọ ninu Rẹ (2ce) 'Gba gbogbo l'o n fi ayọ kun ọkan mi, Tori emi yọ ninu Rẹ. O ti wa mi pe ki n to mọ Ọ, 'Gba ti mo rin jina sagbo, O gbe mi wa sile l'apa Rẹ, Nibi ti papa tutu wa, Emi yọ ninu Rẹ (2ce) 'Gba gbogbo l'o n fi ayọ kun ọkan mi, Tori emi yọ ninu Rẹ. Ore at'anu Rẹ yi mi ka, Or'-ọfẹ Rẹ n san bi odo, Ẹmi Rẹ n tọ, o si n se 'tunu, O ba mi lọ sibikibi; Emi yọ ninu Rẹ (2ce) 'Gba gbogbo l'o n fi ayọ kun ọkan mi, Tori emi yọ ninu Rẹ. Emi y'o dabi Rẹ n'ijọ kan, O s'ẹru wuwo mi kalẹ, Titi 'gbana n ó j'olotitọ, Ni sise ọsọ f'ade rẹ Emi yọ ninu Rẹ (2ce) 'Gba gbogbo l'o n fi ayọ kun ọkan mi, Tori emi yo ninu Rẹ. AMIN
Hymn 580 – OKAN mi yo ninu Oluwa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia