Hymn 579 – NINU oru ibanuje | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "NINU oru ibanuje" (C&S Hymn #579, Yoruba). NINU oru ibanujẹ, L'awọn ẹgbẹ ero n rin; Wọn n kọrin 'reti at'ayọ, Wọn n lọ…
NINU oru ibanujẹ, L'awọn ẹgbẹ ero n rin; Wọn n kọrin 'reti at'ayọ, Wọn n lọ silẹ ileri. Niwaju wa nin' okunkun, Ni imọlẹ didan n tan; Awọn arakunrin n satẹ, Wọn n rin lọ ni aifoya. Ọkan mi imọlẹ ọrun, Ti n tan s'ara eniyan Rẹ; Ti n le gbogbo ẹru jina, Ti n dan yi ọna wa ka. Ọkan ni iro ajo wa, Ọkan ni igbagbọ wa; Ọkan l'ẹni t'a gbẹkẹle, Ọkan ni ireti wa. Ọkan l'orin t'ẹgbẹrun n kọ, Bi lati ọkan kan wa, Ọkan n'ija, ọkan l'ewu, Ọkan ni irin ọrun. Ọkan ni inu didun wa, L'ebute ainipẹkun, Nibi ti Baba wa ọrun, Y'o ma jọba titi lai. Njẹ k'a ma n sọ arakunrin, T'awa ti agbelebu, Ẹ jẹ k'a ru, k'a si jiya, Ti t'a o fi ri 'sinmi. Ajinde nla fẹrẹ de na, Boji fẹrẹ si silẹ, Gbogbo okun y'o si tuka, Gbogbo lala y'o si tan. AMIN
Hymn 579 – NINU oru ibanuje | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia