Hymn 573 – HA! egbe mi, e w'asia | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "HA! egbe mi, e w'asia" (C&S Hymn #573, Yoruba). HA! ẹgbẹ mi, ẹ w'asia, Bi ti n fẹ lẹlẹ! Ogun Jesu fẹrẹ de na, A fẹrẹ…
HA! ẹgbẹ mi, ẹ w'asia, Bi ti n fẹ lẹlẹ! Ogun Jesu fẹrẹ de na, A fẹrẹ sẹgun! D'odi mu, emi fẹrẹ de,‖ Bẹni Jesu n wi, Ran 'dahun pada s'ọrun pe Awa o dimu. Wo ọpọ ogun ti mbọ wa, Esu n ko wọn bọ; Awọn alagbara n subu, A fẹ damu tan! D'odi mu, emi fẹrẹ de,‖ Bẹni Jesu n wi, Ran 'dahun pada s'ọrun pe Awa o dimu. Wo asia Jesu ti n fẹ; Gbọ ohun ipe; A o sẹgun gbogbo ọta, Ni orukọ Rẹ. D'odi mu, emi fẹrẹ de,‖ Bẹni Jesu n wi, Ran 'dahun pada s'ọrun pe Awa o dimu. Ogun n gbo'na girigiri, Iranwọ wa mbọ; Balogun wa mbọ wa tete, Ẹgbẹ tujuka! D'odi mu, emi fẹrẹ de,‖ Bẹni Jesu n wi, Ran 'dahun pada s'ọrun pe Awa o dimu. AMIN
Hymn 573 – HA! egbe mi, e w'asia | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia