Hymn 572 – EYIN ero nibo l' n lo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EYIN ero nibo l' n lo" (C&S Hymn #572, Yoruba). ẸYIN ero nibo l'ẹ n lọ, T'ẹyin t'asia lọwọ? Awa n lọ s'orere ayé, Lati…

Hymn 572 – EYIN ero nibo l' n lo | C&S Yoruba Hymnary
ẸYIN ero nibo l'ẹ n lọ, T'ẹyin t'asia lọwọ? Awa n lọ s'orere ayé, Lati kede ọrọ na. Awa Ọmọ Ẹgbẹ Séráfù, Ti Ọlọrun tun gbe dide, Awa si n jo, awa si n yọ ) Fun ore t'a gba lọfẹ ) 2ce Ẹyin agba, ẹyin ewe, Ẹ ba wa kọ orin na, At'ọkunrin at'obinrin, K'a jọ jumọ juba Rẹ, Awa Ọmọ Ẹgbẹ Séráfù, Ti Ọlọrun tun gbe dide, Awa si n jo, awa si n yọ ) Fun ore t'a gba lọfẹ ) 2ce Ẹyin Ẹgbẹ Onigbagbọ, T'o wa ni gbogbo ayé; Ka fi keta gbogbo silẹ, K'a f'ọmọnikeji wa. Awa Ọmọ Ẹgbẹ Séráfù, Ti Ọlọrun tun gbe dide, Awa si n jo, awa si n yọ ) Fun ore t'a gba lọfẹ ) 2ce f Ẹ wa ka jumọ k'ẹgbẹ lọ, Wa si ẹgbẹ Séráfù; Wa ma kalọ, wa ma kalọ, Gbogbo wa ni Jesu n pe. Awa Ọmọ Ẹgbẹ Séráfù, Ti Ọlọrun tun gbe dide, Awa si n jo, awa si n yọ ) Fun ore t'a gba lọfẹ ) 2ce AMIN Awa Ọmọ Ẹgbẹ Séráfù, Ti Ọlọrun tun gbe dide, Awa si n jo, awa si n yọ ) Fun ore t'a gba lọfẹ ) 2ce

Hymn 572 – EYIN ero nibo l' n lo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia