Hymn 571 – DIDAN l'opagun wa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "DIDAN l'opagun wa" (C&S Hymn #571, Yoruba). DIDAN l'ọpagun wa, O n tọka s'ọrun, O n fọna han ogun, s'ile wọn ọrun!…

Hymn 571 – DIDAN l'opagun wa | C&S Yoruba Hymnary
DIDAN l'ọpagun wa, O n tọka s'ọrun, O n fọna han ogun, s'ile wọn ọrun! Larin aginju l'a n rin, l'ayọ l'a n gbadura, Pẹl' ọkan isọkan l'a 'm' ọn' ọrun pọn, Didan l'ọpagun wa, O n tọka s'ọrun, O n fọna han ogun, s'ile wọn ọrun. Jesu Oluwa wa, l'ẹsẹ Rẹ ọwọ, Pẹlu ọkan ayọ l'ọmọ Rẹ pade, p A ti fi Ọ silẹ, a si ti sako, Tọ wa Olugbala si ọna toro, Didan l'ọpagun wa, O n tọka s'ọrun, O n fọna han ogun, s'ile wọn ọrun. Tọ wa l'ọjọ gbogbo l'ọna t'awa n tọ, Mu wa nso s'isẹgun l'ori ọta wa; di K'Angeli Rẹ s'asa wa gb'oju ọrun su; Dariji, si gba wa l'akoko iku. Didan l'ọpagun wa, O n tọka s'ọrun, O n fọna han ogun, s'ile wọn ọrun. K'a le pẹlu awọn Angel l'oke, Lati jumọ ma yin n'itẹ ifẹ Rẹ, Gba t'ajo wa ba pin, isinmi y'o de, At' alafia, at'orin ailopin. Didan l'ọpagun wa, O n tọka s'ọrun, O n fọna han ogun, s'ile wọn ọrun. AMIN Didan l'ọpagun wa, O n tọka s'ọrun, O n fọna han ogun, s'ile wọn ọrun.

Hymn 571 – DIDAN l'opagun wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia