Hymn 057 – GBA wa lojo na t'a o se 'dajo aye | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "GBA wa lojo na t'a o se 'dajo aye" (C&S Hymn #057, Yoruba). 1. GBA wa lọjọ na t'a o se 'dajọ ayé, K'awa le j'ẹni…
1. GBA wa lọjọ na t'a o se 'dajọ ayé, K'awa le j'ẹni 'tẹwọgba Se iranlọwọ fun wa ka j'ẹni 'tẹwọgba, Sibi omi 'ye t'O pese. Saanu fun wa gbadura wa, Ji ọkan ti n togbe kuro nin'ẹsẹ (2) 2. Jọwọ tan imọlẹ Rẹ loni, Oluwa, S'oju awọn ti ko riran, Ni apa Jesu aye wa sibẹ Mase tun wi awawi mọ. 3. Ẹyin Imale ati Keferi, Ẹ wa gbọ ihin rere yi, Akoko naa mbọ t'a o bere lọwọ rẹ, Pe isẹ kini iwọ n se. 4. Ẹyin Ijọ Kérúbù ati Séráfù, Ẹ j'arọwa ẹ ma w'ẹyin, Lọ wo Isaiah ori ọgọta, Ẹsẹ kini ati keji. 5. Ẹyin ero iworan ati ẹni joko, Bi'dajọ ba ọ nin' ẹsẹ nkọ? Ẹ wa si imọlẹ ninu Ijọ Séráfù, Kẹ ba le jẹni 'tẹwọgba 6. Gbogbo Ọmọ Ijọ t'o s'olotito, Ade ogo ti wa fun yin, Bohubiea Aleakutatabb, Ko ni jẹ ki gbogbo wa segbe. 7. Ẹyin agan to wa ninu Ijọ, Ẹ mura si 'gbagbọ, Ki ẹ le ni ọmọ bi Samuẹli, Lọdọ Olodumare. 8. Ẹyin Alamọdi to wa nin' Ẹgbẹ, Ẹyin yoo si ri 'wosan gba, Lat'ọdọ onisegun Jerusalẹmu Ẹ o ri imularada. 9. Ẹyin ti ẹ ko ti ri'sẹ se, Jehofa Jireh yoo pese, Isẹ rere fun itẹlọrun yin, Ẹ o si ri 'tunu gba. 10. Ogo ni fun Baba loke, Ogo ni fun Ọmọ, Ogo ni fun Ẹmi-Mimọ, Mẹtalọkan lailai. Saanu fun wa gbadura wa, Ji ọkan ti n togbe kuro nin'ẹsẹ (2) AMIN
Hymn 057 – GBA wa lojo na t'a o se 'dajo aye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia