Hymn 058 – OBA ti ki ye majemu | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OBA ti ki ye majemu" (C&S Hymn #058, Yoruba). 1. ỌBA ti ki yẹ majẹmu, F'ore ọfẹ Rẹ fun wa, Majẹmu ti a ba Ọ da, Ki awa…
1. ỌBA ti ki yẹ majẹmu, F'ore ọfẹ Rẹ fun wa, Majẹmu ti a ba Ọ da, Ki awa ko le mu sẹ. Nitori iku Messiah ) Jọwọ ko sanu fun wa )2ce 2. Ọba Mimọ Ọba Ogo, 'Wọ l'awa n fi iyin fun, Kérúbù ati Séráfù, S'ọpẹ ọdun titun yi. 3. Alaileso jẹ k'o s'eso, Ninu ọdun t'a wa yi, Alaigbagbọ jẹ ko gbagbọ, Ki gbogbo wa di yiye. 4. Ọba Mimọ Jehofa NLA Gb'ọpẹ Ajọdun wa yi, Sẹri ibukun Rẹ sori, Ọmọde at'agba wa. 5. Pese f'awọn alairise, Pese ọmọ fun agan, Fi ilera fun alaisan, K'ọmọ Rẹ mase rahun AMIN
Hymn 058 – OBA ti ki ye majemu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia