Hymn 568 – EMI 'ba le f'iwa pele | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EMI 'ba le f'iwa pele" (C&S Hymn #568, Yoruba). EMI 'ba le f'iwa pẹlẹ, Ba Ọlọrun mi rin; Ki n ni imọlẹ ti n tọ mi,…
EMI 'ba le f'iwa pẹlẹ, Ba Ọlọrun mi rin; Ki n ni imọlẹ ti n tọ mi, Sọdọ Ọdaguntan! Ibukun ti mo ni ha da, 'Gba mo kọ mọ Jesu? Itura ọkan na ha da, T'ọrọ Kristi fun mi? Alafia mi nigba naa, 'Ranti rẹ ti dun to! Sugbọn wọn ti b'afo silẹ, Ti ayé ko le di. Pada, Ẹmi Mimọ pada, Ojisẹ itunu: Mo ko ẹsẹ t'o bi Ọ n'nu, T'o le Ọ lọkan mi. Oosa ti mo fẹ rekọja, Ohun t'o wu k'o jẹ, Ba mi yọ kuro lọkan mi; Ki n le sin 'Wọ nikan. Bayi ni n ó b'Ọlọrun rin, Ara o rọ mi wọ! 'Mọlẹ ọrun y'o ma tọ mi, Sọdọ Ọdaguntan. AMIN
Hymn 568 – EMI 'ba le f'iwa pele | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia