Hymn 569 – JESU mimo, Ore airi | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JESU mimo, Ore airi" (C&S Hymn #569, Yoruba). JESU mimọ, Ọrẹ airi, Oluranlọwọ alaini; N'nu ayida ayé, kọ mi, K'emi le…

Hymn 569 – JESU mimo, Ore airi | C&S Yoruba Hymnary
JESU mimọ, Ọrẹ airi, Oluranlọwọ alaini; N'nu ayida ayé, kọ mi, K'emi le rọ mọ Ọ. Ki n sa n'idapọ mimọ yi, Gba ohun t'O fẹ n ó kun bi? B'ọkan mi, b'ẹka ajara, Ba sa le rọ mọ Ọ. Arẹ ti m'ọkan mi pupọ, Sugbọn o wa r'ibi 'sinmi, Ibukun si de s'ọkan mi, 'Tori t'o rọ mọ Ọ. B'ayé d'ofo mọ mi loju, B' a gba ọrẹ at' ara lo, di Ni suru ati laibohun, L'emi o rọ mọ Ọ. Gba t'o k'emi nikansoso, L'arin idamu ayé yi, Mo gb'ohun ifẹ jẹjẹ na, Wi pé, ―Sa rọ mọ Mi. B'arẹ ba fẹ mu igbagbọ, T'ireti ba si fẹ saki, Ko si ewu fun ọkan na, T'o ba rọ mọ Ọ. Ko bẹru irumi ayé, Nitori 'Wọ wa nitosi; Ki O si gbọn b'iku ba de, 'Tori o rọ mọ Ọ. Irẹ sa ni l'ohun gbogbo, 'Wọ agbara at'asa mi, Olugbala, ki y'o si nkan, Bi mba ti rọ mọ Ọ. AMIN

Hymn 569 – JESU mimo, Ore airi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia