Hymn 567 – ESE d'eru? Wo, Jesu ni | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ESE d'eru? Wo, Jesu ni" (C&S Hymn #567, Yoruba). ESE d'ẹru? Wo, Jesu ni! Oun tikarẹ l'o n tọkọ; Ẹ ta 'bokun si afẹfẹ,…

Hymn 567 – ESE d'eru? Wo, Jesu ni | C&S Yoruba Hymnary
ESE d'ẹru? Wo, Jesu ni! Oun tikarẹ l'o n tọkọ; Ẹ ta 'bokun si afẹfẹ, Ti y'o gbe wa la ibu, Lọ si ilu, 'Bit' olofo ye sọkun. B'a ko mọ 'bi t'a n lọ gun si, Ju b'a ti n gbohin rẹ lọ; Sugb' a ko'hun gbogbo silẹ, A tẹle ihin t'a gbọ; Pẹlu Jesu, A nla arin ibu lọ. A ko bẹru igbi okun, A ko si ka iji si; Larin 'rukerudo k'a mọ P'Oluwa mbẹ nitosi, Okun gba gbọ, Iji sa niwaju Rẹ. B'ayọ wa o ti to lọhun, Iji ki ja de ibẹ, Nibẹ l'awọn ti n sọta wa, Ko le yọ wa lẹnu mọ. Wahala pin, L'ebute alafia na. AMIN

Hymn 567 – ESE d'eru? Wo, Jesu ni | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia