Hymn 566 – AMONA okan at'Oga | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "AMONA okan at'Oga" (C&S Hymn #566, Yoruba). AMỌNA ọkan at'Ọga, Awọn ero l'ọna ọrun, Jọ ba wa gbe, ani awa, T'a gbẹkẹle…
AMỌNA ọkan at'Ọga, Awọn ero l'ọna ọrun, Jọ ba wa gbe, ani awa, T'a gbẹkẹle Iwọ nikan; Iwọ nikan l'a f'ọkan sọ, B'a ti n rin l'ọna ayé yi. Alejo at'ero l'a jẹ, A mọ p'ayé ki ise 'le wa; Wawa l'a n rin 'lẹ osi yi, L'aisinmi l'a n wa oju Rẹ; A n yara s'ilu wa ọrun, Ile wa titi lailai l'oke. Iwọ ti o ru ẹsẹ wa, T'o si fi gbogbo rẹ ji wa; f Nipa Rẹ l'a n lọ si Sion, T'a n duna ile wa ọrun; Afin Ọba wa ologo, O n sunmọ wa, b'a ti n kọrin. Nipa imisi ifẹ Rẹ, A mu ọna ajo wa pọn: S'idapọ Ijọ-akọbi, A n rin lọ si oke ọrun, T'awa t'ayọ ni orin wa. Lati pade Balogun wa. AMIN
Hymn 566 – AMONA okan at'Oga | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia