Hymn 565 – E MA te siwaju, Kristian ologun | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "E MA te siwaju, Kristian ologun" (C&S Hymn #565, Yoruba). Ẹ MA tẹ siwaju, Kristian ologun, Ma tejumọ Jesu t'o mbẹ…
Ẹ MA tẹ siwaju, Kristian ologun, Ma tejumọ Jesu t'o mbẹ niwaju; Kristi Oluwa wa ni Balogun wa, Wo! asia Rẹ wa niwaju ogun Ẹ ma tẹ siwaju, Kristian ologun, Sa tẹjumọ, Jesu t'o mbẹ niwaju. Ni orukọ Jesu, ogun Esu sa, Njẹ Kristian Ologun, ma nso si sẹgun; Ọrun apadi mi ni hiho iyin, Ara, gbohun yin ga, gb'orin yin soke. Ẹ ma tẹ siwaju, Kristian ologun, Sa tẹjumọ, Jesu t'o mbẹ niwaju. Bi ẹgbẹ ogun nla, n'Ijọ Ọlọrun, Ara, a rin l'ọna t'awọn mimọ rin; A ko ya wa n'ipa, ẹgbẹ kan ni wa, Ọkan n'ireti, l'ẹkọ, ọkan n'ifẹ. Ẹ ma tẹ siwaju, Kristian ologun, Sa tẹjumọ, Jesu t'o mbẹ niwaju. Itẹ at' Ijọba, wọnyi le parun, Sugbọn Ijọ Jesu y'o wa titi lai. Ọrun apadi ko le bor' Ijọ yi, A n' ileri Kristi, eyi ko le yẹ. Ẹ ma tẹ siwaju, Kristian ologun, Sa tẹjumọ, Jesu t'o mbẹ niwaju. Ẹ ma ba ni kalọ, ẹyin eniyan, D'ohun yin pọ mọ wa, l'orin isẹgun; Ogo, iyin, ọla fun Kristi Ọba, Eyi ni y'o ma jẹ orin wa titi. Ẹ ma tẹ siwaju, Kristian ologun, Sa tẹjumọ, Jesu t'o mbẹ niwaju. AMIN Ẹ ma tẹ siwaju, Kristian ologun, Sa tẹjumọ, Jesu t'o mbẹ niwaju.
Hymn 565 – E MA te siwaju, Kristian ologun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia