Hymn 564 – OLUSAGUNTAN y'o pese | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLUSAGUNTAN y'o pese" (C&S Hymn #564, Yoruba). OLUSAGUNTAN y'o pese, Y'O fi papa tutu bọ mi, Ọwọ rẹ y'o mu 'ranwọ wa,…

Hymn 564 – OLUSAGUNTAN y'o pese | C&S Yoruba Hymnary
OLUSAGUNTAN y'o pese, Y'O fi papa tutu bọ mi, Ọwọ rẹ y'o mu 'ranwọ wa, Oju rẹ y'o si ma sọ mi, Y'o ma ba mi kiri lọsan. Loru y'o ma dabobo mi. Nigba ti mo n rare kiri, Ninu isina l'aginju, O mu mi wa si pẹtẹlẹ, O fi ẹsẹ mi le ọna; Nib' odo tutu n san pẹlẹ, Larin papa oko tutu. Bi mo tilẹ n rin kọja lọ, Ni afonifoji iku, Emi ki o bẹru-kẹru, 'Tori Iwọ wa pẹlu mi, Ọgọ at'ọpa Rẹ y'o mu Mi la ojiji iku ja. Lẹhin ara ija lile, 'Wọ tẹ tabili kan fun mi; Ire at'anu ni mo n ri, Ago mi si n kun wọ silẹ: 'Wọ fun mi n'ireti ọrun, Ibugbe ayérayé mi. AMIN

Hymn 564 – OLUSAGUNTAN y'o pese | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia