Hymn 554 – JESU, ma to wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU, ma to wa" (C&S Hymn #554, Yoruba). JESU, ma tọ wa, Tit' a o fi sinmi, Bi ọna wa ko tilẹ dan, A o tẹle Ọ laifoya;…
JESU, ma tọ wa, Tit' a o fi sinmi, Bi ọna wa ko tilẹ dan, A o tẹle Ọ laifoya; F'ọwọ Rẹ tọ wa, S' ilu Baba wa. B'ọna ba lewu, B'ọta sunmọ wa, Ma jẹ k'aigbagbọ m'ẹru wa, Ki 'gbagbọ oun 'reti yẹ; Tor' arin ọta, La n lọ s'ile wa. Gba t'a fẹ 'tunu, Ninu 'banujẹ, Gba t'idanwo titun ba de, Oluwa, fun wa ni suru; F' ilu ni han wa, Ti ẹkun ko si. Jesu, ma tọ wa, Tit' a o fi ni sinmi: Amọna ọrun, tọju wa, Dabobo wa, tọju wa, Titi a o fi de, Ilu Baba wa. AMIN
Hymn 554 – JESU, ma to wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia