Hymn 555 – JESU ni Balogun oko | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JESU ni Balogun oko" (C&S Hymn #555, Yoruba). JESU ni Balogun ọkọ, Ẹ mase jẹ k'a foya, Olutọkọ wa ni Jesu, Ẹ mase jẹ…

Hymn 555 – JESU ni Balogun oko | C&S Yoruba Hymnary
JESU ni Balogun ọkọ, Ẹ mase jẹ k'a foya, Olutọkọ wa ni Jesu, Ẹ mase jẹ k'a foya, Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu l'ọga ọkọ, Bo ti wu ki 'ji naa le to, Yoo mu ọkọ wa gunlẹ. Ẹyin ero to wa l'ọkọ, Ẹ ke pe Jesu nikan;' K'ẹ si gbẹkẹle yin le pẹlu, Yoo mu ọkọ wa gunlẹ. Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu l'ọga ọkọ, Bo ti wu ki 'ji naa le to, Yoo mu ọkọ wa gunlẹ. Olugbala 'Wọ t'ọrọ Rẹ, Mu igb' omi pa rọrọ, Iwọ t'o rin lori omi, T'o sun bẹni ko si nkan? Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu l'ọga ọkọ, Bo ti wu ki 'ji naa le to, Yoo mu ọkọ wa gunlẹ. Ki l'ohun to n ba yin lẹru? Ẹyin ọmọgun Kristi, Bi Jesu ba wa 'nu ọkọ, Awa yoo fi 'gbi rẹrin. Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu l'ọga ọkọ, Bo ti wu ki 'ji naa le to, Yoo mu ọkọ wa gunlẹ. 'Gbati 'gbi ayé yi ba n ja, Lor' okun ati nilẹ; Abo kan mbẹ ti o daju, Lọdọ Olugbala wa. Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu l'ọga ọkọ, Bo ti wu ki 'ji naa le to, Yoo mu ọkọ wa gunlẹ. Lọwọ kiniun at' ẹkun, Lọwọ ẹranko ibi, Jesu yoo dabobo tirẹ, Jesu yo pa tirẹ mọ. Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu l'ọga ọkọ, Bo ti wu ki 'ji naa le to, Yoo mu ọkọ wa gunlẹ. Mẹtalọkan Alagbara, Dabobo awa ọmọ rẹ; Lọwọ atẹgun ati iji, Jẹ k'awa k' alleluyah. Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu l'ọga ọkọ, Bo ti wu ki 'ji naa le to, Yoo mu ọkọ wa gunlẹ. Ogo ni fun Baba loke, Ogo ni fun Ọmọ Rẹ, Ogo ni fun Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan l'ọpẹ yẹ. Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu l'ọga ọkọ, Bo ti wu ki 'ji na le to, Yoo mu ọkọ wa gunlẹ. AMIN Ẹ mase bẹru, Ẹ kun fun ayọ, Nitori Jesu l'ọga ọkọ, Bo ti wu ki 'ji na le to, Yoo mu ọkọ wa gunlẹ.

Hymn 555 – JESU ni Balogun oko | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia