Hymn 546 – GEGE bi oro ore Re | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "GEGE bi oro ore Re" (C&S Hymn #546, Yoruba). GẸGẸ bi ọrọ ore Rẹ, Ninu irẹlẹ nla, Emi o s'eyi, Oluwa, Emi o ranti Rẹ.…

Hymn 546 – GEGE bi oro ore Re | C&S Yoruba Hymnary
GẸGẸ bi ọrọ ore Rẹ, Ninu irẹlẹ nla, Emi o s'eyi, Oluwa, Emi o ranti Rẹ. Ara Rẹ ti a bu fun mi, Yoo jẹ Ounjẹ mi, Mo gba ago majẹmu Rẹ, Lati se ranti Rẹ. Mo le gbagbe Getsemane, Ti mo r'ijanu Rẹ, Iya oun ogun ẹjẹ Rẹ, Ki n ma si ranti Rẹ? N ó ranti gbogbo rora Rẹ, Ati 'fẹ Rẹ si mi; Bi o ku emi kan fun mi, Emi o ranti Rẹ. 'Gbati ẹnu mi ba pamọ, Ti iye mi ba ra, Ti O ba de n' IjỌba Rẹ, Jesu, jọ ranti mi. AMIN

Hymn 546 – GEGE bi oro ore Re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia