Hymn 547 – JESU, ayo okan gbogbo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU, ayo okan gbogbo" (C&S Hymn #547, Yoruba). JESU, ayọ ọkan gbogbo, Orisun 'ye, imọlẹ wa, Nin' ọpọ bukun ayé yi,…
JESU, ayọ ọkan gbogbo, Orisun 'ye, imọlẹ wa, Nin' ọpọ bukun ayé yi, Lainitẹlọrun: a tọ wa. Otitọ rẹ duro lailai, 'Wọn gba awọn to ke pe Ọ la, Awọn ti o wa Ọ, ri Ọ, Bi gbogbo nin' ohun gbogbo A tọ Ọ wa, Ounjẹ iye, A fẹ jẹ l'arẹ Rẹ titi, A mu ninu Rẹ, Orisun, Lati pa oungbẹ ọkan wa. Oungbẹ Rẹ sa n gbẹ ọkan wa, Nibikibi t'o wu k'a wa; 'Gba t'a ba ri Ọ awa yọ, Ayọ nigba t'a gba Ọ gbọ. Jesu, wa ba wa gbe titi, Se akoko wa ni rere; Le okunkun ẹsẹ kuro, Tan 'mọlẹ Rẹ mimọ s'ayé. AMIN
Hymn 547 – JESU, ayo okan gbogbo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia