Hymn 545 – BABA orun! emi fe wa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "BABA orun! emi fe wa" (C&S Hymn #545, Yoruba). m BABA ọrun! emi fẹ wa, N' iwa mimọ l' ododo: Sugbọn ifẹ ẹran-ara, Ntan…

Hymn 545 – BABA orun! emi fe wa | C&S Yoruba Hymnary
m BABA ọrun! emi fẹ wa, N' iwa mimọ l' ododo: Sugbọn ifẹ ẹran-ara, Ntan mi jẹ nigba gbogbo. Alailera ni emi se, Ẹmi mi at' ara mi, Ẹsẹ gba gbogbo ti mo n da, Wọ mi l'ọrun bi ẹru nla. Ofin kan mbẹ ni ọkan mi, 'Wọ papa l'o fi sibẹ; 'Tori eyi ni mo fi fẹ, Tẹle 'fẹ at' asẹ Rẹ. Sibẹ, bi mo fẹ se rere, Lojukan naa, mo sina; Rere l'ọrọ Rẹ ma sọ, Buburu l'emi si n se. Nigba pupọ ni mo n jọwọ, Ara mi fun idanwo: Bi a tilẹ n kilọ fun mi, Lati gafara f'ẹsẹ. Baba ọrun, Iwọ nikan, L'o to lati gba mi la; Olugbala ti o ti ran, Oun na ni n ó gba mọra. Fi Ẹmi Mimọ Rẹ tọ mi, S'ọna titun ti mba gba: Kọ mi, sọ mi, k'O si tọ mi Iwọ Ẹmi Ọlọrun. AMIN

Hymn 545 – BABA orun! emi fe wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia