Hymn 544 – JESU n pe wa, losan, loru | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU n pe wa, losan, loru" (C&S Hymn #544, Yoruba). JESU n pe wa, lọsan, loru, Larin irumi ayé; Lojojumọ l'a n gbohun…
JESU n pe wa, lọsan, loru, Larin irumi ayé; Lojojumọ l'a n gbohun Rẹ, Wi pé, Kristian, tẹle Mi. Awọn Aposteli gbani, Ni odo Galili ni: Wọn kọ ile, ọna, silẹ, Gbogbo wọn si n tọ lẹhin. Jesu n pe wa, kuro ninu Ohun ayé asan yi; Larin afẹ ayé, O n wi, Pe, Kristian ẹ fẹran Mi. Larin ayọ at' ẹkun wa, Larin lala oun 'rọrun; Tantan l'o n pe l'ohun rara, Pe, Kristian ẹ fẹran Mi, Olugbala nip' anu Rẹ, Jẹ ki a gbọ ipe Rẹ, F' eti 'gbọran fun gbogbo wa, K'a fẹ Ọ ju ayé lọ. AMIN
Hymn 544 – JESU n pe wa, losan, loru | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia