Hymn 533 – IFE to fi wa emi ti eru ese n pa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "IFE to fi wa emi ti eru ese n pa" (C&S Hymn #533, Yoruba). IFẸ to fi wa ẹmi ti ẹru ẹsẹ n pa, O fi ọwọ Rẹ fa mi mọra…

Hymn 533 – IFE to fi wa emi ti eru ese n pa | C&S Yoruba Hymnary
IFẸ to fi wa ẹmi ti ẹru ẹsẹ n pa, O fi ọwọ Rẹ fa mi mọra pada s'agbo; Angeli n fi ayọ kọrin pẹlu awọn ogun ọrun. A! Ifẹ t'o wa mi, A! Ẹjẹ t'o ra mi, A! Suru pẹlu ore-ọfẹ Rẹ, T'o fa mi pada bọ, wa s'agbo! O w' ẹsẹ mi nu kuro k'emi Le di mimọ, O sọ fun mi jẹjẹ pe- ―Iwọ sa jẹ t'emi‖ Ko si ohun to dun t'eyi lo mu alarẹ ọkan yọ. A! Ifẹ t'o wa mi, A! Ẹjẹ t'o ra mi, A! Suru pẹlu ore-ọfẹ Rẹ, T'o fa mi pada bọ, wa s'agbo! Emi y'o wa si 'hin yi, ile ọwọ mimọ, Pẹlu ọkan igbagbọ, lati tọrọ 'bukun; O dabi ẹni pe ọjọ n gun lati fi iyin Rẹ han. A! Ifẹ t'o wa mi, A! Ẹjẹ t'o ra mi, A! Suru pẹlu ore-ọfẹ Rẹ, T'o fa mi pada bọ, wa s'agbo! Njẹ nigba t'orun ba wọ, t'ọjọ oni si lọ, N ó se 'reti owurọ ti yoo mu ayọ wa! Titi a o fi pe mi lati bọ sinu isinmi Rẹ. A! Ifẹ t'o wa mi, A! Ẹjẹ t'o ra mi, A! Suru pẹlu ore-ọfẹ Rẹ, T'o fa mi pada bọ, wa s'agbo! AMIN A! Ifẹ t'o wa mi, A! Ẹjẹ t'o ra mi, A! Suru pẹlu ore-ọfẹ Rẹ, T'o fa mi pada bọ, wa s'agbo!

Hymn 533 – IFE to fi wa emi ti eru ese n pa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia