Hymn 534 – KERUBU ati Serafu | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "KERUBU ati Serafu" (C&S Hymn #534, Yoruba). KÉRÚBÙ ati Séráfù, Ẹ fẹran ara yin, Gẹgẹ bi awọn t'ọrun, Ti fẹran ara wọn.…
KÉRÚBÙ ati Séráfù, Ẹ fẹran ara yin, Gẹgẹ bi awọn t'ọrun, Ti fẹran ara wọn. K'a gbẹkẹle Jesu, Oluwa Mimọ ni, Bi mo t'ni ifẹ Jesu, Emi ko le segbe. Ọta pọ fun wa layé, Ko si alabaro; Jesu l'Olubanidaro, Oun naa lo le gba wa. K'a gbẹkẹle Jesu, Oluwa Mimọ ni, Bi mo t'ni ifẹ Jesu, Emi ko le segbe. Esu ti korira wa, O fẹ mu wa dani; Sugbọn ewo la o se, Jesu ti pẹlu wa. K'a gbẹkẹle Jesu, Oluwa Mimọ ni, Bi mo t'ni ifẹ Jesu, Emi ko le segbe. Jesu ti sẹgun esu, L' or' oke Kalfari; Oluwa sẹgun fun wa, Ka le bori ọta wa. K'a gbẹkẹle Jesu, Oluwa Mimọ ni, Bi mo t'ni ifẹ Jesu, Emi ko le segbe. Ọlọrun Orimolade, Jọwọ saanu fun wa; K'O gba wa lọw' ọta wa, Ni ọna wa gbogbo. K'a gbẹkẹle Jesu, Oluwa Mimọ ni, Bi mo t'ni ifẹ Jesu, Emi ko le segbe. Ni akoko iku wa Mu ki ọkan wa mọ; Ka ba le lọ ri Jesu, Lọdọ Baba loke K'a gbẹkẹle Jesu, Oluwa Mimọ ni, Bi mo t'ni ifẹ Jesu, Emi ko le segbe. A ki Baba Aladura; Ti Baba gbe dide; Ki Jesu ko ran lọwọ Ko gbe ọwọ rẹ soke. K'a gbẹkẹle Jesu, Oluwa Mimọ ni, Bi mo t'ni ifẹ Jesu, Emi ko le segbe. Jehovah Rufi, Baba, Gb' adura Ijọ yi, Jehovah Jire Mimọ, K'O mẹsẹ wa duro. K'a gbẹkẹle Jesu, Oluwa Mimọ ni, Bi mo t'ni ifẹ Jesu, Emi ko le segbe. Ẹyin ijọ Aladura, Ẹ mura si isẹ yin; K'ẹ n'ifẹ si ara yin; Baba yoo gbọ tiyin. K'a gbẹkẹle Jesu, Oluwa Mimọ ni, Bi mo t'ni ifẹ Jesu, Emi ko le segbe. A f'ogo fun Baba loke, A f'ogo f'Ọmọ Rẹ, A f'ogo F'Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan lailai. K'a gbẹkẹle Jesu, Oluwa Mimọ ni, Bi mo t'ni ifẹ Jesu, Emi ko le segbe. AMIN K'a gbẹkẹle Jesu, Oluwa Mimọ ni, Bi mo t'ni ifẹ Jesu, Emi ko le segbe.
Hymn 534 – KERUBU ati Serafu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia