Hymn 532 – 'FE enikeji re | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "'FE enikeji re" (C&S Hymn #532, Yoruba). 'FẸ ẹnikeji rẹ, Asẹ Oluwa ni; O wa f'ara Rẹ s'apẹrẹ, Ni fifẹ t'O fẹ wa. Fẹ…
'FẸ ẹnikeji rẹ, Asẹ Oluwa ni; O wa f'ara Rẹ s'apẹrẹ, Ni fifẹ t'O fẹ wa. Fẹ ẹnikeji rẹ, N'ire tabi n'ija; O kọ wa pe k'a f'ọta wa, K'a f'ore san ibi. Fẹ enikeji rẹ. Oluwa n ke tantan; O yẹ ki gbogbo wa mura, K'a f'ẹnikeji wa. Fẹ ẹnikeji rẹ, At' aladugbo rẹ, Pẹlu gbogb' ẹni yi ọ ka, At' ọta rẹ pẹlu. K'a f'ẹnikeji wa, Bi Jesu ti fẹ wa, Jesu sa f'awọn ọta Rẹ, O si sure fun wọn. AMIN
Hymn 532 – 'FE enikeji re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia