Hymn 528 – ALABUKUN ni fun ife | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "ALABUKUN ni fun ife" (C&S Hymn #528, Yoruba). ALABUKUN ni fun ifẹ, Ti ki o jẹ k'a ya; Bi ara wa jina s'ara, Ọkan wa wa…
ALABUKUN ni fun ifẹ, Ti ki o jẹ k'a ya; Bi ara wa jina s'ara, Ọkan wa wa l'ọkan. Da ọpọ Ẹmi s'ori wa, Ọna t'O la l'a n tọ; Nipa ti Jesu l'a si n rin, Iyin Rẹ l'a n fi han. Awa ba ma rin l'ọna Rẹ, K'a ma si m'ohun kan, K'a ma fẹ 'hun kan, bikose, Jesu t'a pa fun wa. K'a sunmọ Ọ girigiri, Ati si ọna Rẹ; K'a ma r'ore gba lọdọ Rẹ, Ẹkun ore-ọfẹ. AMIN
Hymn 528 – ALABUKUN ni fun ife | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia