Hymn 527 – ARA, e je ka jumo rin | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ARA, e je ka jumo rin" (C&S Hymn #527, Yoruba). ARA, ẹ jẹ ka jumọ rin, N'ifẹ oun alafia; A ha le ma tun bere pe, O tọ…

Hymn 527 – ARA, e je ka jumo rin | C&S Yoruba Hymnary
ARA, ẹ jẹ ka jumọ rin, N'ifẹ oun alafia; A ha le ma tun bere pe, O tọ k'a ba f'ija mọ? Ni irẹpọ, ni irẹpọ, L'ayọ, ifẹ y'o fi pọ. B'a ti n rin lọ sile, jẹ ka, Ran 'ra wa lọwọ l'ọna; Ọta ka wa nibi gbogbo; S'ọna gbogbo l'a dẹkun, Isẹ wa ni, isẹ wa ni, K'a ma ran 'ra wa l'ẹru. Nigba t'a rohun Baba se, T'o ti fi ji, t'o n fiji, Ara, ko tọ k'awa k'o kọ Lati ma f'ija silẹ? K'a mu kuro, k'a mu kuro, Ohun 'ba mu 'binu wa. K'a gb'ọmọnikeji wa ga, Ju b'a ba ti gbe 'ra wa , K'a fi keta gbogbo silẹ, K'ọkan wa si kun fun 'fẹ, Yoo rọ wa, yoo rọ wa, B'a wa n'irẹpọ layé. AMIN

Hymn 527 – ARA, e je ka jumo rin | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia