Hymn 526 – JESU, Iwo ni a n wo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JESU, Iwo ni a n wo" (C&S Hymn #526, Yoruba). JESU, Iwọ ni a n wo, K'a rẹ pọ l'orukọ Rẹ, Alade alafia; Mu k'ija tan…

Hymn 526 – JESU, Iwo ni a n wo | C&S Yoruba Hymnary
JESU, Iwọ ni a n wo, K'a rẹ pọ l'orukọ Rẹ, Alade alafia; Mu k'ija tan l'arin wa. Nipa ilaja Tirẹ, Mu idugbolu kuro; Jẹ k'a dapọ si ọkan; F'itẹgun Rẹ sarin wa. Jẹ k'a wa ni ọkan kan, K'a se anu at'ore, K'a tutu l'ero, l'ọkan, Gẹgẹ bi Oluwa wa. K'a s'aniyan ara wa, K'a ma rẹru ara wa, K'a f'apẹrẹ fun Ijọ, B'Olugbagbọ ti gbe pọ. K'a kuro ni ibinu; K'a sinmi le Ọlọrun, K'a sọ ti ibu ifẹ, At'iwa giga mimọ. K'a f'ayọ kuro layé, Lọ si ijọ ti ọrun; K'a f'iyẹ Angẹli fo, K'a le ku b'ẹni mimọ. AMIN

Hymn 526 – JESU, Iwo ni a n wo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia