Hymn 525 – 'GBAT' AYE yi ba koja | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "'GBAT' AYE yi ba koja" (C&S Hymn #525, Yoruba). 'GBAT' AYÉ yi ba kọja, T'orun re ba si wọ, Ti a ba wọ 'nu ogo, T'a…

Hymn 525 – 'GBAT' AYE yi ba koja | C&S Yoruba Hymnary
'GBAT' AYÉ yi ba kọja, T'orun re ba si wọ, Ti a ba wọ 'nu ogo, T'a boju wo ẹhin wa, 'Gbana, Oluwa, n o mọ, Bi gbese mi ti pọ to. 'Gba mo ba de b'itẹ Rẹ, 'Lẹwa ti ki se t'emi, 'Gba mo ri Ọ b'O ti ri, Ti mo fẹ Ọ l'afẹtan; 'Gbana, Oluwa , n ó mọ, Bi gbese mi ti pọ to. 'Gba mba n gbọ orin ọrun, Ti n dun bi ohun ara, Bi iro omi pupọ, T'o sin dun b'ohun duru, 'Gbana, Oluwa n ó mọ, Bi gbese mi ti pọ to. Oluwa, jọ, jẹ k'a ri Ojiji Rẹ l'ayé yi; K'a mo adun 'dariji, Pẹlu iranwọ Ẹmi; Ki n tilẹ mọ l'ayé yi, Diẹ ninu 'gbese mi. Ore-ọfẹ l'o yan mi, L'o yọ mi ninu ewu; Jesu l'Olugbala mi, Ẹmi sọ mi di mimọ, Kọ mi, ki n fihan l'ayé, Bi gbese mi ti pọ to! AMIN

Hymn 525 – 'GBAT' AYE yi ba koja | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia