Hymn 524 – O FUN mi l'edidi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "O FUN mi l'edidi" (C&S Hymn #524, Yoruba). O FUN mi l'edidi, 'Gbese nla ti mo jẹ, B'o ti fun mi, o si rẹrin, Pe, Mase…
O FUN mi l'edidi, 'Gbese nla ti mo jẹ, B'o ti fun mi, o si rẹrin, Pe, Mase gbagbe mi! O fun mi l'edidi, O san igbese na; B'o ti fun mi, O si rẹrin, Wi pé, ―Ma ranti mi! N ó p'edidi na mọ, B'igbese tilẹ tan; O n sọ ifẹ ẹni t'o san, Igbese naa fun mi. Mo wo, mo si rẹrin Mo tun wo, mo sọkun; Ẹri ifẹ Rẹ si mi ni, N ó tọju rẹ titi. Ki tun s'edidi mọ, Sugbọn iranti ni! Pe gbogbo igbese mi ni, Emmanueli san. AMIN
Hymn 524 – O FUN mi l'edidi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia