Hymn 529 – ALAFIA ni f'okan na | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ALAFIA ni f'okan na" (C&S Hymn #529, Yoruba). ALAFIA ni f'ọkan na; Nibi ti 'fẹ gbe wa, Kérúbù pẹlu Séráfù, Ẹ fẹran ara…

Hymn 529 – ALAFIA ni f'okan na | C&S Yoruba Hymnary
ALAFIA ni f'ọkan na; Nibi ti 'fẹ gbe wa, Kérúbù pẹlu Séráfù, Ẹ fẹran ara yin. Gẹgẹ bi Kérúbù ọrun, Pẹlu Seraf' ọrun; Awọn ni wọn yi 'tẹ na ka, Wọn yin Baba logo. Asan ni gbogbo 'gbagbọ jẹ, Bi ko si 'fẹ nibẹ; Ẹsẹ yoo jọba lọkan wa, B' ifẹ ko si nibẹ. Ifẹ nikan ni yoo r'opin, Ẹ fẹran ara yin, Ma banujẹ, ma b'ohun bọ, Ade yoo jẹ tiwa. Sugbọn ifẹ ni n wi bayi, Ẹ fẹran ara yin; Nipa ifẹ a o ri Baba, L'oke ọrun lọhun. Jehovah-Nissi Baba wa, Pe wa n' Tirẹ loke; Ẹmi Mimọ 'daba ọrun, Jọwọ f'ọna han ni. Jesu Olugbala, ọwọn, Fun Kérúbù n' ifẹ, Gẹgẹ bi Kérúbù ọrun, Pẹlu Seraf' ọrun. Jehovah-Rufi Baba wa, Fun wa l'ọkun 'lera; Ka le jọ fi 'yin fun Baba, Gẹgẹ b'awọn t'ọrun. AMIN

Hymn 529 – ALAFIA ni f'okan na | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia