Hymn 519 – JESU, Oluwa, a fe O | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU, Oluwa, a fe O" (C&S Hymn #519, Yoruba). JESU, Oluwa, a fẹ Ọ, 'Tori gbogbo ẹbun, N t'ọwọ Rẹ da lat' oke wa, B'…
JESU, Oluwa, a fẹ Ọ, 'Tori gbogbo ẹbun, N t'ọwọ Rẹ da lat' oke wa, B' iri si gbogb' ayé, A yin Ọ nitori wọnyi; K' ise fun wọn nikan, Ni awọn ọmọ-ọdọ Rẹ, Se ń gbadura si Ọ. Awa fẹ Ọ, Olugbala, 'Tori 'gba t'a sako; Iwọ pe ọkan wa pada, Lati t'ọna iye, 'Gba t'a wa ninu okunkun, T'a rin ninu ẹsẹ: 'Wọ ran imọlẹ Rẹ si wa, Lati f'ọna han wa. Baba ọrun, awa fẹ Ọ, Nitori 'Wọ fẹ wa; 'Wọ ran Ọmọ Rẹ lati ku, Ki awa le n'iye, 'Gbat'a wa labẹ 'binu Rẹ, 'Wọ fun wa n'ireti; Bi ẹsẹ t'a da ti pọ to, Bẹ l'o dariji wa. AMIN
Hymn 519 – JESU, Oluwa, a fe O | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia