Hymn 518 – ORUKO kan mbe ti mo fe | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ORUKO kan mbe ti mo fe" (C&S Hymn #518, Yoruba). ORUKỌ kan mbẹ ti mo fẹ, Mo fẹ ma kọrin rẹ, Iro didun ni l'eti mi,…

Hymn 518 – ORUKO kan mbe ti mo fe | C&S Yoruba Hymnary
ORUKỌ kan mbẹ ti mo fẹ, Mo fẹ ma kọrin rẹ, Iro didun ni l'eti mi, Orukọ didun ni. O sọ ifẹ Olugbala, T'o ku lati ra mi; O sọ t'ẹjẹ Rẹ 'yebiye, Etutu f'ẹlẹsẹ. O sọ ti yọnu Baba, T'O ni s'ọmọ Rẹ; O m'ara mi ya, lati la Aginju ayé ja. Jesu, Orukọ ti mo fẹ, T'o si dun l'eti mi; Ko s'ẹni mimọ kan l'ayé, T'o mọ b'o ti pọ to. Orukọ yi j'orun didun, L'ọna ẹgun t'a ń rin, Yoo tun ọna yangi se, T'o lọ s'ọdọ Ọlọrun. Nibẹ pẹlu awọn mimọ, Ti wọn 'bọ nin' ẹsẹ? Emi o kọrin titun ni, T'ifẹ Jesu si mi. AMIN

Hymn 518 – ORUKO kan mbe ti mo fe | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia