Hymn 520 – AWA ko orin ife Re | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "AWA ko orin ife Re" (C&S Hymn #520, Yoruba). AWA kọ orin ifẹ Rẹ Ọbangiji Ọba Ogo; Ko s'ohun ti lalasi Rẹ, Ọla Rẹ ko si…
AWA kọ orin ifẹ Rẹ Ọbangiji Ọba Ogo; Ko s'ohun ti lalasi Rẹ, Ọla Rẹ ko si nipẹkun. N'nu ifẹ l'o s'ẹda ayé, O da eniyan sinu rẹ; Lati ma s'akoso gbogbo; Ẹ kọrin 'fẹ Ẹlẹda wa. Lojojumọ l'O n tọju wa, O si mbọ, O si n sikẹ wa, Bẹni ko gba n kan lọwọ wa, Kọrin 'yin s'onibu ọrẹ. O ri wa ninu okunkun, Pe, a ko mọ ojubọ Rẹ; N'ifẹ O fi ọna han wa; Ẹ kọrin ifẹ Olore! N'ifẹ O fi Jesu fun wa, Ọmọ bibi Rẹ kansoso; O wa ra wa lọwọ ẹsẹ, A yin 'fẹ Rẹ Olugbala! Ifẹ Rẹ ran Ọrọ Rẹ wa, Ifẹ Rẹ l'o si wa leti, Ifẹ Rẹ si mu wa duro, Ẹ kọrin ore- ọfẹ Rẹ. Gbogbo ẹda kun fun 'fẹ Rẹ, Oluwa wa, Ọba ayé; Gbogbo agbayé, ẹ gberin, Orin ifẹ Ọlọrun wa. AMIN
Hymn 520 – AWA ko orin ife Re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia