Hymn 513 – N O feran Re, 'wo odi mi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "N O feran Re, 'wo odi mi" (C&S Hymn #513, Yoruba). N Ó fẹran Rẹ, 'wọ odi mi; N ó fẹran Rẹ, 'wọ ayọ mi, N ó fẹran Rẹ,…
N Ó fẹran Rẹ, 'wọ odi mi; N ó fẹran Rẹ, 'wọ ayọ mi, N ó fẹran Rẹ, patapata, N ó fẹran Rẹ, tor'ise Rẹ, N ó fẹran Rẹ, tit'ọkan mi, Y'o fi kun fun ifẹ rere. 'Wọ Orun mi, gba ọpẹ mi, Fun 'mọlẹ Rẹ t'o fi fun mi, Gba ọpẹ mi, 'wọ l'o gba mi, Lọwọ awọn ti n sọta mi; Gba ọpẹ mi, fun ohun Rẹ, T'o mu mi yọ lọpọlọpọ. N'nu ire-ije mi l'ayé, Ma se alabojuto mi; Fi agbara fun ẹsẹ mi, Ki n le t'ẹsẹ m'ọna rere; Ki mba le f'ipa mi gbogbo; F'orukọ Rẹ t'o l'ogo han. N ó fẹran Rẹ, 'Wọ ade mi, N ó fẹran Rẹ, Oluwa mi; N ó fẹran Rẹ, nigba gbogbo L'ọjọ ibi, l'ọjọ ire, 'Gbati ọjọ iku ba de, N ó fẹran Rẹ titi lailai. AMIN
Hymn 513 – N O feran Re, 'wo odi mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia