Hymn 514 – JESU, kiki ironu Re | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU, kiki ironu Re" (C&S Hymn #514, Yoruba). JESU, kiki ironu Rẹ, Fi ayọ kun ọkan; Sugbọn k'a ri Ọ lo dun ju, K'a…
JESU, kiki ironu Rẹ, Fi ayọ kun ọkan; Sugbọn k'a ri Ọ lo dun ju, K'a sinmi lọdọ Rẹ. Ẹnu ko sọ, eti ko gbọ, Ko ti ọkan wa ri; Oko, t'o sọwọn, t'o dun bi Ti Jesu Oluwa. Ireti ọkan ti ń kanu, Olore ẹlẹsẹ, O seun f'awọn ti ń wa Ọ, Awọn t'o ri Ọ yọ. Ayọ wọn, ẹnu ko le sọ, Ẹda ko le royin, Ifẹ Jesu b'o ti pọ to. Awọn Tirẹ l'o mọ. Jesu, 'Wọ ma jẹ ayọ wa, 'Wọ sa ni ere wa; Ma jẹ ogo wa nisinyi, Ati titi lailai. AMIN
Hymn 514 – JESU, kiki ironu Re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia