Hymn 512 – Egbe Seraf, e ma beru | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Egbe Seraf, e ma beru" (C&S Hymn #512, Yoruba). Ẹgbẹ Seraf, ẹ ma bẹru, Ki yoo si nkan; B'esu gbe tasi rẹ si wa, Ki yoo…
Ẹgbẹ Seraf, ẹ ma bẹru, Ki yoo si nkan; B'esu gbe tasi rẹ si wa, Ki yoo si nkan; Jesu Kristi l'Ọgagun wa, Yo fo'tẹgun esu tutu Esu yoo wolẹ labẹ Rẹ, Ki yoo si nkan. B'a ba ń rin l'afonifoji, Ki yoo si nkan, B'iku ń pa l'ọtun ń pa l'osi Ki yoo si nkan; Mase foya, Ijọ Seraf, Tẹsiwaju b'ọmọ ogun, Krist' Ọgagun wa niwaju, Ki yoo si nkan. Kil' ohun ti mba yin lẹru, Ẹgbẹ Seraf; 'Gbati Jesu wa pẹlu wa, Ki yoo si nkan; Sa gbadura, tẹ siwaju, Oke nla yoo di pẹtẹlẹ; Ayé ko le ri wa gbe se, Ki yoo si nkan. Ẹgbẹ Seraf, tẹ siwaju, Larin ina, Ina Esu ko le jo wa, Dajudaju, Bi Sedraki, Mesaki ati Abednigo ninu ina, Be la o duro pẹlu Jesu, Ki yoo si nkan. Ẹgbẹ Seraf, ẹ ho f'ayọ, Ki yoo si nkan, Jesu ti fọ 'tẹgun esu, Dajudaju ; Ogo, iyin fun Ọba wa, To ra wa pada lọwọ 'ku, To sọ wa d'ominira lai; Kabiyesi. AMIN
Hymn 512 – Egbe Seraf, e ma beru | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia