Hymn 511 – OLORUN awon baba wa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN awon baba wa" (C&S Hymn #511, Yoruba). ỌLỌRUN awọn baba wa, 'Wọ ha kọ ni Ọlọrun? Ti o da Ọrun oun Ayé, T'o n…

Hymn 511 – OLORUN awon baba wa | C&S Yoruba Hymnary
ỌLỌRUN awọn baba wa, 'Wọ ha kọ ni Ọlọrun? Ti o da Ọrun oun Ayé, T'o n sakoso lori wọn. Dide Iwọ Ọlọrun wa, Tu awọn ọta wa ka, Awa ko lagbara, sugbọn Oju wa mbẹ l'ara Rẹ. 'Wọ l'o l'awọn ọta jade, T'o fi ilẹ yi fun wa; Awa 'ru ọm'Abraham, Abrahamu, ọrẹ Rẹ. Dide Iwọ Ọlọrun wa, Tu awọn ọta wa ka, Awa ko lagbara, sugbọn Oju wa mbẹ l'ara Rẹ. Ninu ilẹ Mimọ Rẹ yi, B'ogun tilẹ de si wa, Gbati awa ba ke pe Ọ, Jọwọ ran 'ranlọwọ Rẹ, Dide Iwọ Ọlọrun wa, Tu awọn ọta wa ka, Awa ko lagbara, sugbọn Oju wa mbẹ l'ara Rẹ. Oluwa wa da wọn l'ẹjọ, Sọ pe tirẹ l'ogun na, Fihan awọn ọta wa pe, Ọlọrun mbẹ fun Israel. Dide Iwọ Ọlọrun wa, Tu awọn ọta wa ka, Awa ko lagbara, sugbọn Oju wa mbẹ l'ara Rẹ. Oluwa, o o ri ogun Rẹ, A n wo 'subu ọta wa, Tal' Ọlọrun t'o dabi Rẹ, Ọlọrun Ọmọ-ogun. Dide Iwọ Ọlọrun wa, Tu awọn ọta wa ka, Awa ko lagbara, sugbọn Oju wa mbẹ l'ara Rẹ. Ẹ dide, ẹ ko ikogun, Ẹyin eniyan Ọlọrun, 'Tori Ọlọrun ti gbeja, Ẹ ho ye si Jehofa. Dide Iwọ Ọlọrun wa, Tu awọn ọta wa ka, Awa ko lagbara, sugbọn Oju wa mbẹ l'ara Rẹ. Lat' oni lọ, a o ma rin, Afonifoj' ibukun, A o si ma fi ibukun, Fun Oluwa titi lai. Dide Iwọ Ọlọrun wa, Tu awọn ọta wa ka, Awa ko lagbara, sugbọn Oju wa mbẹ l'ara Rẹ. AMIN Dide Iwọ Ọlọrun wa, Tu awọn ọta wa ka, Awa ko lagbara, sugbọn Oju wa mbẹ l'ara Rẹ.

Hymn 511 – OLORUN awon baba wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia