Hymn 510 – ASEGUN awon esu | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "ASEGUN awon esu" (C&S Hymn #510, Yoruba). ASẸGUN awọn esu, Asẹgun awọn iku, Oluwa si fi jona, A dupẹ lọwọ Baba. A…
ASẸGUN awọn esu, Asẹgun awọn iku, Oluwa si fi jona, A dupẹ lọwọ Baba. A sẹgun, A sẹgun, Olusẹgun ti de na, K' awọn ajẹ p'agan mọ, Ajasẹgun mbẹ nihin. A sẹgun koto iku, A sẹgun koto esu, Oluwa si di wọn pa A dupẹ lọwọ Baba. A sẹgun, A sẹgun, Olusẹgun ti de na, K' awọn ajẹ p'agan mọ, Ajasẹgun mbẹ nihin. A sẹgun ọfa iku, A sẹgun ọfa esu, Oluwa sọ wọn d'ofo, A dupẹ lọwọ Baba. A sẹgun, A sẹgun, Olusẹgun ti de na, K' awọn ajẹ p'agan mọ, Ajasẹgun mbẹ nihin. Esu ko le l'agbara, Lori Ẹgbẹ Mimọ yi, Ajẹ, oso, sanpọnna, Di tẹmọlẹ l'ẹsẹ wa. A sẹgun, A sẹgun, Olusẹgun ti de na, K' awọn ajẹ p'agan mọ, Ajasẹgun mbẹ nihin. Jah yoo ma s'Alabo wa, Lọwọ ẹmi buburu, Michael Balogun wa, Ti d'oju ẹsẹ bolẹ. A sẹgun, A sẹgun, Olusẹgun ti de na, K' awọn ajẹ p'agan mọ, Ajasẹgun mbẹ nihin. Ajagomom Busawuu, Ajagomom Butari, Ọmọ Mimọ ti sẹgun, A dupẹ lọwọ Baba A sẹgun, A sẹgun, Olusẹgun ti de na, K' awọn ajẹ p'agan mọ, Ajasẹgun mbẹ nihin. Ayọ ni fun wa loni, Laholah, ẹ bu s'ayọ, Jesu Balogun nla wa, Ti sẹgun iku fun wa. A sẹgun, A sẹgun, Olusẹgun ti de na, K' awọn ajẹ p'agan mọ, Ajasẹgun mbẹ nihin. AMIN A sẹgun, A sẹgun, Olusẹgun ti de na, K' awọn ajẹ p'agan mọ, Ajasẹgun mbẹ nihin.
Hymn 510 – ASEGUN awon esu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia