Hymn 509 – OMO Egbe Kerubu jade | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OMO Egbe Kerubu jade" (C&S Hymn #509, Yoruba). ỌMỌ Ẹgbẹ Kérúbù jade, Gbogbo ajẹ pagan mọ, Awa Séráfù l'o pejọ, Lati…
ỌMỌ Ẹgbẹ Kérúbù jade, Gbogbo ajẹ pagan mọ, Awa Séráfù l'o pejọ, Lati gb'ogo Jesu ga. Maikeli Mimọ Ni Balogun Ẹgbẹ wa (2ce) Ajẹ ko le ri wa gbese, Labẹ ọpagun Jesu, Niwaju awọn Séráfù, Gbogbo ajẹ a fo lọ. Maikeli Mimọ Ni Balogun Ẹgbẹ wa (2ce) Idarudapọ yoo b'ajẹ, Niwaju ogun Jesu, Idaj' Ọlọrun de ba wọn, Lagbara Mẹtalọkan. Maikeli Mimọ Ni Balogun Ẹgbẹ wa (2ce) Halleluya! Halleluya! Jẹ k'a kọ Halleluyah, Ajẹkajẹ ko lagbara, Lori Ijọ Kérúbù, Maikeli Mimọ Ni Balogun Ẹgbẹ wa (2ce) Gidigbo, gidigbo heyai A p'awọn ajẹ n'ija, Ati sọnpọnna baba wọn, Lorukọ Mẹtalọkan. Maikeli Mimọ Ni Balogun Ẹgbẹ wa (2ce) Ẹ f'ogo fun Baba loke, Ẹ f'ogo fun Ọmọ Rẹ, Ẹ f'ogo fun Ẹmi Mimọ F'ogo fun Mẹtalọkan. Maikeli Mimọ Ni Balogun Ẹgbẹ wa (2ce) AMIN Maikeli Mimọ Ni Balogun Ẹgbẹ wa (2ce)
Hymn 509 – OMO Egbe Kerubu jade | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia