Hymn 505 – GBOGBO Egbe Seraf' to wa ni gbogb aye | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "GBOGBO Egbe Seraf' to wa ni gbogb aye" (C&S Hymn #505, Yoruba). GBOGBO Ẹgbẹ Seraf' to wa ni gbogb ayé, Ẹ sin Olugbala…

Hymn 505 – GBOGBO Egbe Seraf' to wa ni gbogb aye | C&S Yoruba Hymnary
GBOGBO Ẹgbẹ Seraf' to wa ni gbogb ayé, Ẹ sin Olugbala l'emi at'otọ, E fi keta sile, e feran ara yin, Gbogbo wa ni Jesu Olugbala n pe. Wa k'a jumọ rin, wa k'a jumọ rin, Wa si Ẹgbẹ Seraf' ati Kérúbù, Wa k'a jumọ rin, wa ka jumọ rin, Wa si Ẹgbẹ Seraf' wa gb'ẹmi rẹ la. Nigba t'ayé ti sẹ ti awa ti d'ayé, A gbọ wi pé Jesu lo sẹgun Esu; Awa Ẹgbẹ Seraf' y'o si sẹgun Esu, Ni Orukọ Ọlọrun Mẹtalọkan. Wa k'a jumọ rin, wa k'a jumọ rin, Wa si Ẹgbẹ Seraf' ati Kérúbù, Wa k'a jumọ rin, wa ka jumọ rin, Wa si Ẹgbẹ Seraf' wa gb'ẹmi rẹ la. Awọn Ajẹ, Oso, ko ni agbara kan, Lori Ẹgbẹ Seraf' ati Kérúbù, Ẹgbẹ aladura, ẹ damure giri, K'a le sẹgun Esu pẹlu ogun rẹ. Wa k'a jumọ rin, wa k'a jumọ rin, Wa si Ẹgbẹ Seraf' ati Kérúbù, Wa k'a jumọ rin, wa ka jumọ rin, Wa si Ẹgbẹ Seraf' wa gb'ẹmi rẹ la. Ẹyin Ẹgbẹ Akọrin, ẹ tun ohun yin se, Lati yin Olugbala wa ni ogo; Gbogb' awọn t'o ti ja, wọn si sẹgun esu, Mura k'ẹyin na le sẹgun bi ti won. Wa k'a jumọ rin, wa k'a jumọ rin, Wa si Ẹgbẹ Seraf' ati Kérúbù, Wa k'a jumọ rin, wa ka jumọ rin, Wa si Ẹgbẹ Seraf' wa gb'ẹmi rẹ la. Ayé le ma kẹgan, wọn si le ma sata, Sugbọn Séráfù mọ Ẹni t'oun n sin, Iwọ m'Ẹni ti o n sin, Ẹni t'o n sin mọ ọ, Sa tẹjumọ Jesu, iwọ yoo sẹgun Wa k'a jumọ rin, wa k'a jumọ rin, Wa si Ẹgbẹ Seraf' ati Kérúbù, Wa k'a jumọ rin, wa ka jumọ rin, Wa si Ẹgbẹ Seraf' wa gb'ẹmi rẹ la. Nigba t'a ba pari isẹ wa ni ayé, A o gb'ade lẹhin irin ajo wa; Jesu Olugbala, yoo ko wa de Keniyan, 'Lẹ ileri na ti Ọga Ogo. Wa k'a jumọ rin, wa k'a jumọ rin, Wa si Ẹgbẹ Seraf' ati Kérúbù, Wa k'a jumọ rin, wa ka jumọ rin, Wa si Ẹgbẹ Seraf' wa gb'ẹmi rẹ la. AMIN Wa k'a jumọ rin, wa k'a jumọ rin, Wa si Ẹgbẹ Seraf' ati Kérúbù, Wa k'a jumọ rin, wa ka jumọ rin, Wa si Ẹgbẹ Seraf' wa gb'ẹmi rẹ la.

Hymn 505 – GBOGBO Egbe Seraf' to wa ni gbogb aye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia