Hymn 504 – AW' OMO ogun Oba ti a f'eje Re ra | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "AW' OMO ogun Oba ti a f'eje Re ra" (C&S Hymn #504, Yoruba). AW' ỌMỌ ogun Ọba ti a f'ẹjẹ Rẹ ra, A si mura lati jagun…
AW' ỌMỌ ogun Ọba ti a f'ẹjẹ Rẹ ra, A si mura lati jagun fun Kristi Oluwa, A n gb'arin ọta wa, sugbọn a n f'ayọ kọrin, Ọkan wa yoo duro gbọnin-gbọnin, Awa ọmọ ogun Ọba, Awa ọmọ ogun Ọba, A o kọrin iyin Rẹ, A o si ja tọkan-tọkan, F'Ọba Ologo julọ. Aw' ọmọ ogun Ọba, a o f'ayọ j'oko Rẹ, O kọ ẹni ti a kan mọ'gi, gba Kristi Ọba a mbẹ, Adanu l'ere ayé' a o f'ayọ gba iya, Lati bọwọ f'orukọ Rẹ, b'ọmọ ogun Ọba. Awa ọmọ ogun Ọba, A o kọrin iyin Rẹ, A o si ja tọkan-tọkan, F'Ọba Ologo julọ. Awa ọmọ ogun Ọba, a o jade pẹlu Rẹ, Bi awa ba le ba jiya, k'a si ru itiju, K'a gb'asia Rẹ ga, 'tori akoko n lọ, A ti gba ade n sunmọle, f'awọn ọmọ ogun Ọba, Awa ọmọ ogun Ọba, A o kọrin iyin Rẹ, A o si ja tọkan-tọkan, F'Ọba Ologo julọ. AMIN Awa ọmọ ogun Ọba, A o kọrin iyin Rẹ, A o si ja tọkan-tọkan, F'Ọba Ologo julọ.
Hymn 504 – AW' OMO ogun Oba ti a f'eje Re ra | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia