Hymn 503 – ISE wa gbogbo ti awa n se | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ISE wa gbogbo ti awa n se" (C&S Hymn #503, Yoruba). ISẸ wa gbogbo ti awa n se, Ni Jesu Oluwa ti mọ; Isẹgun ti a fi fun…

Hymn 503 – ISE wa gbogbo ti awa n se | C&S Yoruba Hymnary
ISẸ wa gbogbo ti awa n se, Ni Jesu Oluwa ti mọ; Isẹgun ti a fi fun wa, Ere ti a fi fun asẹgun. Ka dide ka tun hamọra, Ohun wọnni, T'Ọlọrun pe wa si 'ja; Ẹ sa wa wo bo ti dara, Ere ta fi fun asẹgun, (2) Bo ti dara a to, bo ti lọla a to (2) Ere ti a fi fun asẹgun, (2) Ja 'lẹmi ati lotọ, Ọlọrun yoo ran ọ lọwọ; Ma s' pa ọmọnikeji rẹ, Idariji yoo wa fun ọ. Ka dide ka tun hamọra, Ohun wọnni, T'Ọlọrun pe wa si 'ja; Ẹ sa wa wo bo ti dara, Ere ta fi fun asẹgun, (2) Bo ti dara a to, bo ti lọla a to (2) Ere ti a fi fun asẹgun, (2) Sisẹ, sisẹ, igbala rẹ, S'ore ko si ma sanu; Isẹ ti eniyan ba se ninu ayé yi, L'Ọlọrun Baba n fi gba wa . Ka dide ka tun hamọra, Ohun wọnni, T'Ọlọrun pe wa si 'ja; Ẹ sa wa wo bo ti dara, Ere ta fi fun asẹgun, (2) Bo ti dara a to, bo ti lọla a to (2) Ere ti a fi fun asẹgun, (2) Ja bi ọmọ ogun Kristi, Mase gbagbe 'da rẹ silẹ; Ẹni sẹgun lere na wa fun, Ere ti a fi fun asẹgun. Ka dide ka tun hamọra, Ohun wọnni, Bi o ti dara to, B'o ti lọla to, Ijọ Kérúbù ati Séráfù. AMIN Ka dide ka tun hamọra, Ohun wọnni, Bi o ti dara to, B'o ti lọla to, Ijọ Kérúbù ati Séráfù.

Hymn 503 – ISE wa gbogbo ti awa n se | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia