Hymn 506 – KERUBU e ro, Serafu e yo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "KERUBU e ro, Serafu e yo" (C&S Hymn #506, Yoruba). KÉRÚBÙ ẹ yọ, Séráfù ẹ yọ, F'Ẹgbẹ Mimọ yi ti Baba fun wa, T'o ju…
KÉRÚBÙ ẹ yọ, Séráfù ẹ yọ, F'Ẹgbẹ Mimọ yi ti Baba fun wa, T'o ju ọgbọn ati ero ẹda lọ, Ogo, Iyin, Ọla fun Mẹtalọkan. Ẹda ko nipa lori Ẹgbẹ yi, Sa ma se rere iwọ yoo sẹgun, Ma si se fi Ẹda se 'gbẹkẹle Rẹ, Ọlọrun Ẹlẹda ko ni gbagbe Rẹ. Ajẹ ko n'ipa lori Ijọ yi, Oso ko n'ipa lori Ijọ yi, Sa tẹle ọna t'Oluwa la silẹ, Isẹgun y'o jẹ tirẹ lọna gbogbo. Kérúbù ń kigbe, Ẹda ko mira Séráfù n kigbe, Ẹda ko bere, Awawi ko ni si fun yin lọjọ na, T'ẹda a' Angẹli yoo pẹlu dandan. Olodumare gbọ adura mi, Ki n le tẹle Ọ d'opin ayé mi, K'oju ma ti mi ni opin ayé mi, Ki n gbọ, o se ọmọ, bọ si ayọ rẹ. 'Gbana la o kọ'rin Halleluyah, Ni 'waju itẹ Olodumare, T'Olugbala y'o tan mọlẹ Rẹ si wa, K'ori awa mase kọ'ye ainipẹkun. Ogo fun Baba, Ogo fun Ọmọ, Ogo f'Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan, B'ero ẹda ko tilẹ mọ 'jinlẹ Rẹ A o ma yin Ọ sibẹ titi ayé. AMIN
Hymn 506 – KERUBU e ro, Serafu e yo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia