Hymn 483 – MO n lo, talaka mi mbe lodo yin | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "MO n lo, talaka mi mbe lodo yin" (C&S Hymn #483, Yoruba). MO n lọ, talaka mi mbẹ lọdọ yin, Ẹ le ma sore fun wọn b'ẹ ti…

Hymn 483 – MO n lo, talaka mi mbe lodo yin | C&S Yoruba Hymnary
MO n lọ, talaka mi mbẹ lọdọ yin, Ẹ le ma sore fun wọn b'ẹ ti n fẹ. mf Eyi ni ogun t'Olugbala wa, Fi silẹ f'awọn Tirẹ, k'o to lọ. Wura oun jufu kọ, otosi ni, K'a ma ran wọn lọwọ nitori Rẹ. Ẹru nla ko, ogun t'o l'ọrọ ni, Ti n f'ilọpo 'bukun f'ẹni n tọrẹ. T'iwa k'ise naa bi? L'ojude wa, Kọ ni talaka at'asagbe wa? Ohun irora awọn t'iya n jẹ, Ko ha n ke si wa lati f'anu han? Ọkan t'o gb'ọgbẹ, ọkan ti n sisẹ; Ẹkun opo, at'alaini baba! Oun t'o f'ara Rẹ fun wa, si ti fi, Etu ọrun f'awa iransẹ Rẹ. Ko s'otosi kan ti ko le sajo, F'ẹni tosi ju lọ; agbara ni. Isin mimọ ailabawọn l'eyi, Ti Baba mbere lọwọ gbogbo wa. AMIN

Hymn 483 – MO n lo, talaka mi mbe lodo yin | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia