Hymn 482 – OGO fun Jesu f'anu Re lofe | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OGO fun Jesu f'anu Re lofe" (C&S Hymn #482, Yoruba). OGO fun Jesu f'anu Rẹ lọfẹ, Anu lọfẹ, anu lọfẹ, Ẹlẹsẹ anu n san,…
OGO fun Jesu f'anu Rẹ lọfẹ, Anu lọfẹ, anu lọfẹ, Ẹlẹsẹ anu n san, fun ọ lọfẹ, Anu n san pupọ lọfẹ, Bi iwọ ba fẹ lati gba a gbọ, Anu lọfẹ, anu lọfẹ, Iwọ yoo r'iye ainipẹkun gba Anu n san pupọ lọfẹ, Jesu Olugbala n wa o kiri, N wa ọ kiri, n wa ọ kiri, T'anu-t'anu t'ifẹ lo fi n pe ọ O n pe ọ, O n wa ọ kiri. Ẹsẹ to n kiri lokiti ẹsẹ? Anu lọfẹ; anu lọfẹ, Ẹmi n pe ọ jẹjẹ wi pé wa 'le, Anu n san pupọ lọfẹ, O wa n'okun bi? A! wa si 'mọlẹ, Anu lọfẹ, anu lọfẹ, Jesu n duro yoo gba ọ lalẹ yi, Anu n san pupọ lọfẹ. Jesu Olugbala n wa o kiri, N wa ọ kiri, n wa ọ kiri, T'anu-t'anu t'ifẹ lo fi n pe ọ O n pe ọ, O n wa ọ kiri. Ro ti ọre, suru, ati ife Rẹ; Anu lọfẹ, anu lọfẹ, O bẹbẹ fun ọ lọdọ Baba loke, Anu n san pupọ lọfẹ, Wa ronupiwada fun lọkan rẹ Anu lọfẹ, anu lọfẹ, Ma banujẹ sugbọn wa b'o ti ri, Anu n san pupọ lọfẹ, Jesu Olugbala n wa o kiri, N wa ọ kiri, n wa ọ kiri, T'anu-t'anu t'ifẹ lo fi n pe ọ O n pe ọ, O n wa ọ kiri. Njẹ anu wa fun gbogb' ẹni gbagbọ, Anu lọfẹ, anu lọfẹ, Wa k'o si gba 'bukun nisinsin yii Anu n san pupọ lọfẹ, Jesu n duro, A! gbọ b'O ti n kede, Anu lọfẹ, anu lọfẹ, Rọ mọ 'leri Rẹ 'gba Ookọ rẹ gbọ, Anu n san pupọ lọfẹ, Jesu Olugbala n wa o kiri, N wa ọ kiri, n wa ọ kiri, T'anu-t'anu t'ifẹ lo fi n pe ọ O n pe ọ, O n wa ọ kiri. AMIN Jesu Olugbala n wa o kiri, N wa ọ kiri, n wa ọ kiri, T'anu-t'anu t'ifẹ lo fi n pe ọ O n pe ọ, O n wa ọ kiri.
Hymn 482 – OGO fun Jesu f'anu Re lofe | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia