Hymn 484 – OLUWA da agan l'ohun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA da agan l'ohun" (C&S Hymn #484, Yoruba). OLUWA da agan l'ohun, B'o ti da Hannah l'ohun; Ma doju 'gbagbọ ti awọn…

Hymn 484 – OLUWA da agan l'ohun | C&S Yoruba Hymnary
OLUWA da agan l'ohun, B'o ti da Hannah l'ohun; Ma doju 'gbagbọ ti awọn Ti n ke pe orukọ Rẹ. Da mi l'ohun (2) Ki n le ye ma banujẹ. 'Wọ gb' ẹkun Elisabet' Larin awọn ẹlẹgan, O fi Johannu re l'ẹkun, P'ọmọ Rẹ ma sọkun mọ. Rẹ mi l'ẹkun (2) Loju awọn ota mi. Ranti ileri Rẹ 'gbani, At'ire t'O fun Noa, Pe k'ẹ ma bisi, k'ẹ ma rẹ, Ni ori ilẹ ayé. Da mi l'ohun (2) Iwọ Ọba Olore. 'Wọ ti ko jẹ k'ẹran yagan, Tab' ẹyẹ oju ọrun, Sanu f'aworan ara Rẹ, Ki o si si mi ninu. Si mi ninu (2) Ọlọrun Onipin mi. 'Gbati mo ro ọkan mi wo, Mo mọ p'ẹlẹbi ni mi; Mo ti tọ 'pa 'fẹ inu mi, T'o ko wahala ba mi. Dariji mi (2) 'Wọ Oniyọnu julọ. AMIN Dariji mi (2) 'Wọ Oniyọnu julọ.

Hymn 484 – OLUWA da agan l'ohun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia