Hymn 477 – OLUWA jowo pa wa mo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA jowo pa wa mo" (C&S Hymn #477, Yoruba). OLUWA jọwọ pa wa mọ, Iwọ l'awa gbẹkẹle, Ọkan wa wi f'Oluwa pe, Iwọ ni…
OLUWA jọwọ pa wa mọ, Iwọ l'awa gbẹkẹle, Ọkan wa wi f'Oluwa pe, Iwọ ni Ọlọrun wa. A ko ni 're kan lẹhin Rẹ Baba, Iwọ l'awa gbẹkẹle, Mase fi wa silẹ f'ọta, K'asẹgun n'ile l'ode. S'awọn eniyan mimọ Rẹ, Ani s'awọn ọlọla, Bi ẹni ti didun 'nu wa, Yoo ma wa titi lailai. A ko ni 're kan lẹhin Rẹ Baba, Iwọ l'awa gbẹkẹle, Mase fi wa silẹ f'ọta, K'asẹgun n'ile l'ode. Ibinujẹ awọn ti n sa T'Ọlọrun miran yoo pọ, Ẹbọ ohun mim' ẹjẹ wọn, L'emi ki yoo ta silẹ. A ko ni 're kan lẹhin Rẹ Baba, Iwọ l'awa gbẹkẹle, Mase fi wa silẹ f'ọta, K'asẹgun n'ile l'ode. Oluwa n'ipin ini mi, Ati ipin ago mi, Se wọ lo mu 'la mi duro, T'o ko jẹ k'ọta ba jẹ. A ko ni 're kan lẹhin Rẹ Baba, Iwọ l'awa gbẹkẹle, Mase fi wa silẹ f'ọta, K'asẹgun n'ile l'ode. Okun tita bọ s'ọdọ mi, Nibi t'o dara julo, L'otitọ mo fọwọ sọya, Pe mo ni ogun rere, A ko ni 're kan lẹhin Rẹ Baba, Iwọ l'awa gbẹkẹle, Mase fi wa silẹ f'ọta, K'asẹgun n'ile l'ode. Emi o fi 'bukun f'Oluwa, To fun mi ni imọran, Ọkan mi pẹlu sa n ko mi, L'arin wakati oru. A ko ni 're kan lẹhin Rẹ Baba, Iwọ l'awa gbẹkẹle, Mase fi wa silẹ f'ọta, K'asẹgun n'ile l'ode. Mo gb' Oluwa ka 'waju mi, Nibi gbogbo l'ayé mi, 'Tori o wa lọwọ 'tun mi, A ki yoo si mi nipo. A ko ni 're kan lẹhin Rẹ Baba, Iwọ l'awa gbẹkẹle, Mase fi wa silẹ f'ọta, K'asẹgun n'ile l'ode. 'Tori naa n'inu mi se dun, T'ogo mi si n yọ jade, Ara mi pẹlu yoo sinmi, Ni 're ti iye ailopin. A ko ni 're kan lẹhin Rẹ Baba, Iwọ l'awa gbẹkẹle, Mase fi wa silẹ f'ọta, K'asẹgun n'ile l'ode. O ki yoo f'ọkan mi silẹẹ, Ni arin ipo oku, Bẹẹ ni ẹni mimọ tirẹ, Ki yoo ri idibajẹ. A ko ni 're kan lẹhin Rẹ Baba, Iwọ l'awa gbẹkẹle, Mase fi wa silẹ f'ọta, K'asẹgun n'ile l'ode. Mo mọ p'o f'ọna 'ye han mi, Waju Rẹ l'ẹkun ayọ wa , Ni ọwọ ọtun Rẹ sa ni, Didun 'nu mi wa lailai. A ko ni 're kan lẹhin Rẹ Baba, Iwọ l'awa gbẹkẹle, Mase fi wa silẹ f'ọta, K'asẹgun n'ile l'ode. S'alabo Ijọ Séráfù, Ati Ijọ Kérúbù, Awọn to n sin Ọ nitotọ, Nigun mẹrẹrin ayé. A ko ni 're kan lẹhin Rẹ Baba, Iwọ l'awa gbẹkẹle, Mase fi wa silẹ f'ọta,…
Hymn 477 – OLUWA jowo pa wa mo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia