Hymn 476 – OLUWA Olorun gba wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA Olorun gba wa" (C&S Hymn #476, Yoruba). OLUWA Ọlọrun gba wa, Lọwọ iku ojiji, Ọlọrun Olugbala wa, Iwọ l'awa…
OLUWA Ọlọrun gba wa, Lọwọ iku ojiji, Ọlọrun Olugbala wa, Iwọ l'awa gbẹkẹle, Oluwa dabobo wa, Lọwọ ajẹ, at'oso, Isẹ pọ t'awa yoo se, Nitori na da wa si. Da wa si, da wa si, Isẹ pọ t'awa yoo se Nitori na da wa si. Ọlọrun Olodumare, Gba wa lọw' ajakal' arun Ma jẹ ki ẹmi buburu Le wọle tọ Séráfù, Oluwa dabobo wa, Lọwọ ajẹ, at'oso, Isẹ pọ t'awa yoo se, Nitori na da wa si. Da wa si, da wa si, Isẹ pọ t'awa yoo se Nitori na da wa si. Ẹmi Mimọ ko pẹlu wa, L'ọkunrin at'obinrin, Ka le jẹ ti Krist Oluwa, Larin ọdun t'a wa yi, Oluwa dabobo wa, Lọwọ ajẹ, at'oso, Isẹ po t'awa yoo se, Nitori na da wa si. Da wa si, da wa si, Isẹ pọ t'awa yoo se Nitori na da wa si. AMIN Da wa si, da wa si, Isẹ pọ t'awa yoo se Nitori na da wa si.
Hymn 476 – OLUWA Olorun gba wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia