Hymn 475 – LOWO Kiniun at'ekun | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "LOWO Kiniun at'ekun" (C&S Hymn #475, Yoruba). LỌWỌ Kiniun at'ẹkun, Lọwọ ẹranko ibi, Jọ sọ aw' Ijọ Séráfù, At'ọmọ 'jọ…
LỌWỌ Kiniun at'ẹkun, Lọwọ ẹranko ibi, Jọ sọ aw' Ijọ Séráfù, At'ọmọ 'jọ Kérúbù, Ninu gbogbo iji to nja, A! nibo l'a ba sa si, A! Baba ma fi wa silẹ, Sẹgun Satani fun wa. Ko s'ọna ti a ba tun tọ, To le bori ọna yi, Jẹ ka diju si nkan t'ayé, Ka laju si nkan f'ọrun, Ma jẹ k'ayé fa wa s'ẹhin, Kuro ninu ọna Rẹ, N'nu 'banujẹ at'ipọnju, Emi ki o fi Ọ silẹ. Ade ogo yoo jẹ ti yin, T'ẹyin ko ba sin l'ẹtan, Mo se tan mo ti pa yin pọ, Ẹmi ni Ẹmi Airi, Sugbọn mo wa n'nu Ọlanla, Mo le pa, mo le gbala, Jẹ arọwa k'ẹ ma w'ehin, K'ẹ le gbere nikẹhin. Ifẹ to dopin la n tọrọ, Fun gbogb' Ẹgbẹ to papọ, Ẹ ja, ẹ sẹgun, ẹ bori, Layé yi ati lọrun, Sugọn 'danwo tun wa l'ọrun A! bawo ni yoo ti ri, Ka gbọ p'o ti jẹ Séráfù, O tun pada nikẹhin. Ohun ti mo ba pa lasẹ, Ma f'ọgbọn-ori yipada, Ẹni ti ko ba gba 'ran gbọ, O dabi ẹni ti Ọ, Kọ'le rẹ si eti odo, Ẹkun omi de o gba lọ, K'ẹ mase ro p'agbara yin, La ko se fin yin silẹ. Jesu setan lati gba yin, O kun f' anu at'ifẹ, Gb'ara rẹ le patapata, Ma gb'ẹkẹl' ohun miran, Gbohun-gbohun orukọ Rẹ, Si gba gbogbo ọrun kan, Ke Halleluya s'Ọlọrun, Fi 'baralẹ juba Rẹ. Ẹ f'Ogo fun Baba loke, Ẹ f'Ogo fun Ọmọ Rẹ, Mẹtalọkan ayérayé, A juba Orukọ Rẹ, Mase jẹ ki 'pade wa yi, Ko jẹ asan nigbẹhin, F'oju anu wo 'papọ wa, K'a le ma pade titi. AMIN
Hymn 475 – LOWO Kiniun at'ekun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia