Hymn 478 – OLORUN 'Wo l'agbara mi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN 'Wo l'agbara mi" (C&S Hymn #478, Yoruba). ỌLỌRUN 'Wọ l'agbara mi, Emi o fẹran Rẹ; Iwọ l'odi at'abo mi, Ni igba…
ỌLỌRUN 'Wọ l'agbara mi, Emi o fẹran Rẹ; Iwọ l'odi at'abo mi, Ni igba aini mi. Ni 'gba 'rora oun 'banujẹ, Mo tọrọ or'-ọfẹ , Ọlọrun gbọ aroye mi Lat' ibi mimọ Rẹ. Ati ninu ọla-nla Rẹ O gun awọn Kerub' L'apa iyẹ afẹfẹ, L'o si n fo kakiri. O mu mi sibi titẹju, Ki n le di omnira: O si pa mi mọ nitori, Inu Rẹ dun si mi. Ọna Ọlọrun mo pupọ, Ọrọ Rẹ ye koro, Awọn t'o n tẹle ọna Rẹ, Ni abo t'o daju. AMIN
Hymn 478 – OLORUN 'Wo l'agbara mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia