Hymn 469 – OLORUN lo se 'leri ekun igbala | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN lo se 'leri ekun igbala" (C&S Hymn #469, Yoruba). ỌLỌRUN lo se 'leri ẹkun igbala, Pe ẹni to ba gba Jesu Ọmọ Rẹ…

Hymn 469 – OLORUN lo se 'leri ekun igbala | C&S Yoruba Hymnary
ỌLỌRUN lo se 'leri ẹkun igbala, Pe ẹni to ba gba Jesu Ọmọ Rẹ gbọ Halleluyah, O mu sẹ, Mo ti gba Ọmọ gbọ; Mo ti ri 'gbala l'ẹjẹ ni t'a kan mọ 'gi. Anikanrin lọna na o lewu pẹlu Dajudaju Jesu lo le mu wa la ja. Halleluyah, O mu sẹ, Mo ti gba Ọmọ gbọ; Mo ti ri 'gbala l'ẹjẹ ni t'a kan mọ 'gi. Ọpọ olufẹ ti rin 'na ọrun na ri, Wọn ri 'gbala nin' ogo ni orin wọn. Halleluyah, O mu sẹ, Mo ti gba Ọmọ gbọ; Mo ti ri 'gbala l'ẹjẹ ni t'a kan mọ 'gi. Mo ri awọn ọmọde nitosi Ọba na, O ń rẹrin bi wọn ti n kọrin igbala wọn. Halleluyah, O mu sẹ, Mo ti gba Ọmọ gbọ; Mo ti ri 'gbala l'ẹjẹ ni t'a kan mọ 'gi. Awọn Woli at'awọn Ọba pọ lọhun, Wọn n kọrin lopopo ojulowo wura. Halleluyah, O mu sẹ, Mo ti gba Ọmọ gbọ; Mo ti ri 'gbala l'ẹjẹ ni t'a kan mọ 'gi. Egbe orin kan wa, temi tirẹ y'o kọ, Nibi ti a o ma yin titi lailai. Halleluyah, O mu se, Mo ti gba Ọmọ gbọ; Mo ti ri 'gbala l'ẹjẹ ni t'a kan mọ'gi. AMIN Halleluyah, O mu se, Mo ti gba Ọmọ gbọ; Mo ti ri 'gbala l'ẹjẹ ni t'a kan mọ'gi.

Hymn 469 – OLORUN lo se 'leri ekun igbala | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia