Hymn 468 – OLORUN kan lo to k'a sin | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN kan lo to k'a sin" (C&S Hymn #468, Yoruba). ỌLỌRUN kan lo tọ k'a sin, K'a si fẹran Rẹ l'afẹtan; A ko gbọdọ bọ…
ỌLỌRUN kan lo tọ k'a sin, K'a si fẹran Rẹ l'afẹtan; A ko gbọdọ bọ orisa, Nitori ohun asan ni. K'a ranti pe la ti ri igbala, O tọ ka p'ofin mọ, Ti Ọlọrun ti sọ fun wa, Ti Ọlọrun ti sọ fun wa. Kérúbù pẹlu Séráfù, Fẹran ọmọnikeji rẹ, Ifẹ ni awọn Angẹli, Ni wọn fi n sin Baba loke. K'a ranti pe la ti ri igbala, O tọ ka p'ofin mọ, Ti Ọlọrun ti sọ fun wa, Ti Ọlọrun ti sọ fun wa. Baba Aladura mura, Lati pad' awọn Kérúbù, Ade ogo yoo jẹ tirẹ, T'ọmọ arayé ko le gba. K'a ranti pe la ti ri igbala, O tọ ka p'ofin mọ, Ti Ọlọrun ti sọ fun wa, Ti Ọlọrun ti sọ fun wa. Ileri to se fun Mose, Ni ori oke Sinai, T'o pe Oun yoo wa pẹlu rẹ, Lati ko wa de'lẹ Kenani. K'a ranti pe la ti ri igbala, O tọ ka p'ofin mọ, Ti Ọlọrun ti sọ fun wa, Ti Ọlọrun ti sọ fun wa. Agbagba mẹrinlelogun, A juba orukọ nla yin, Ati ẹda 'laye mẹrin Kẹ s'amin si adura wa. K'a ranti pe la ti ri igbala, O tọ ka p'ofin mọ, Ti Ọlọrun ti sọ fun wa, Ti Ọlọrun ti sọ fun wa. Johovah Jire Ọba Wa, Gbadura Ẹgbẹ Kérúbù, Jehovah Nissi Baba wa, Mẹtalọkan gbadura wa. K'a ranti pe la ti ri igbala, O tọ ka p'ofin mọ, Ti Ọlọrun ti sọ fun wa, Ti Ọlọrun ti sọ fun wa. AMIN K'a ranti pe la ti ri igbala, O tọ ka p'ofin mọ, Ti Ọlọrun ti sọ fun wa, Ti Ọlọrun ti sọ fun wa.
Hymn 468 – OLORUN kan lo to k'a sin | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia